Posts

Showing posts from November 11, 2023

UI@75:We’ll refurbish Agbowo Shopping Complex very soon…Makinde

Image
  We’ll refurbish Agbowo Shopping Complex very soon…Makinde ….unveils UI @75 anniversary billboard Oyo State governor, ‘Seyi Makinde, on Saturday, revealed that works will soon begin on Agbowo Shopping Complex, stating that the project remains important to his administration as it is part of its agenda to resuscitate the state’s assets. The governor promised that the contractor of the project will move to site in the next few weeks, just as he promised to carry out the Junction Improvement of the University of Ibadan Main Gate with a pedestrian bridge to link Agbowo axis. Governor Makinde stated this while unveiling the billboard commemorating the UI @ 75 anniversary on the University Campus. He solicited for continuous support and cooperation of the University of Ibadan community, urging it to be patient, as according to him, the disruption of free flow of traffic will be inevitable once the projects start. The governor, while congratulating the school management in achieving mileston

ṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ! By Ayélabégàn Akínkúnmi Baba Awo. Ọ̀kan gbóògì nínú ọmọ ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES Ìwọ̀ -oòrùn Ọ̀yọ́

Image
  B'éwúrẹ́ bá kangídì a dòbúkọ, Àgùtàn kangídì a dàgbò, B'Óbìnrin kangídì a dìyálé, Ìyálé tó bá kangídì ní í m'ètò àsè..! Koríko wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ digbó, Ìrì wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ d'òjò, Ahéré di abà, Abà dìlú ńlá Omi sẹ́lẹ̀rú ṣe bẹ́ẹ̀ ó d'odò tí ń sàn tó ń s'aráyé láńfààní, Ọmọ ìkókó ló pàpà di baba, Aròbó àná ló dìyálé sọ́ọ̀dẹ̀! Iṣẹ́ Akin ló sọ ọmọ Mákindé di àpèwááwò káàkiri ilẹ̀ yìí, Gbogbo ìpínlè ló ń w'ọkọ Olúfúnkẹ́ bí i kó jẹ́ tiwọn, Jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá ni wón ń fẹ Ọmọ Ọlátúbọ̀sún dọ́kàn! Sèyí Mákindé, Ìnáròbó lẹ́nu alátakò àná ti ṣe bẹ́ẹ̀ ó dọ̀gá ńlá! Isẹ́ ribiribi tó f'Akin ṣe ló wú Òṣémàwé lórí, Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ó di JAGUNMÓLÚ l'Óǹdó ẹ̀gin, Ọkọ Olúfúnnkẹ́ ti dolórí oko fún gbogbo wọn, Ọmọ 'Látúbọ̀sún ti sọ àwọn òpè dakúrẹtẹ̀ kalẹ̀. Ẹ wọ̀tún, ẹ tún wòsì wò ná, Ẹ wo 'wájú kí ẹ tún wẹ̀yìn kún, Ẹ wò 'là kẹ́ ẹ tún wò 'wọ̀ oòrùn, Ẹ ṣíjú wo Gúúsù kí ẹ w'àríwá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Ẹ wo bó ṣe sọgbó dilé, Ẹ wo bó ṣe sọ̀ 'gbẹ́ dìgboro, Ẹ rí i bó ṣe sọ