ṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ! By Ayélabégàn Akínkúnmi Baba Awo. Ọ̀kan gbóògì nínú ọmọ ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES Ìwọ̀ -oòrùn Ọ̀yọ́


 



B'éwúrẹ́ bá kangídì a dòbúkọ,

Àgùtàn kangídì a dàgbò,

B'Óbìnrin kangídì a dìyálé,

Ìyálé tó bá kangídì ní í m'ètò àsè..!


Koríko wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ digbó,

Ìrì wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ d'òjò,

Ahéré di abà,

Abà dìlú ńlá

Omi sẹ́lẹ̀rú ṣe bẹ́ẹ̀ ó d'odò tí ń sàn tó ń s'aráyé láńfààní,

Ọmọ ìkókó ló pàpà di baba,

Aròbó àná ló dìyálé sọ́ọ̀dẹ̀!


Iṣẹ́ Akin ló sọ ọmọ Mákindé di àpèwááwò káàkiri ilẹ̀ yìí,

Gbogbo ìpínlè ló ń w'ọkọ Olúfúnkẹ́ bí i kó jẹ́ tiwọn,

Jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá ni wón ń fẹ Ọmọ Ọlátúbọ̀sún dọ́kàn!




Sèyí Mákindé, Ìnáròbó lẹ́nu alátakò àná ti ṣe bẹ́ẹ̀ ó dọ̀gá ńlá!

Isẹ́ ribiribi tó f'Akin ṣe ló wú Òṣémàwé lórí,

Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ó di JAGUNMÓLÚ l'Óǹdó ẹ̀gin,

Ọkọ Olúfúnnkẹ́ ti dolórí oko fún gbogbo wọn,

Ọmọ 'Látúbọ̀sún ti sọ àwọn òpè dakúrẹtẹ̀ kalẹ̀.


Ẹ wọ̀tún, ẹ tún wòsì wò ná,

Ẹ wo 'wájú kí ẹ tún wẹ̀yìn kún,

Ẹ wò 'là kẹ́ ẹ tún wò 'wọ̀ oòrùn,

Ẹ ṣíjú wo Gúúsù kí ẹ w'àríwá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́,

Ẹ wo bó ṣe sọgbó dilé,

Ẹ wo bó ṣe sọ̀ 'gbẹ́ dìgboro,

Ẹ rí i bó ṣe sọ gbogbo àkìtàn ilẹ̀ yìí dọjà tó ń tà wàràwàrà!


Ṣèyí kúrò láròbó,

Ọpọlọ pípé lọmọ Májọlágbé fi ń ṣiṣẹ́ ọba,

Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun tó fi ń sìnlú ti pọ̀tá lẹ́numọ́,

Wọ́n ò sọ̀tẹ̀ mọ́, 

Àní wọ́n ti gbáròyé tì!


A dúpẹ́ nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́,

A ò gbé aṣọ wa rán fónígbàjámọ̀,

A ò gbé irun orí fún kanlékanlé,

A ò bẹ fọganáísà pé kó báwa tún ìlẹ̀kùn wa ṣe!


Ọ̀bẹ kò ṣe é gé 'gi

Àáké kò ṣe é hó'sàn

Àdá kò dùn ún fárí rárá

Olórí pípé la gbéṣẹ́ fún nìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,

Abìwà pẹ̀lẹ́ bí orí adẹ́tù

Olúṣèyí Abíọ́dún ọmọ Mákindé

Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ nikán ń mọlé,

Pẹ̀lẹ́pùtù là á yọ'ṣẹ̀ lẹ́kù,

Máa ṣe wẹ́rẹ́ forí pípé tukọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ yìí nìsó,

Igbá oyin lo gbé, o ò gbé 'gbá ata!

Mùmùràrà layé ń dẹ̀wá lọ́rùn.


Ṣèyí Mákindé JAGUNMÓLÚ,


Oyè á mọ́rí ooooo!

Comments

Popular posts from this blog

Just in : Olubadan of Ibadanland Oba Mohood Lekan Balogun Joins Ancestors