Èké dáyé, aásà dàpòmu, ìgbà yí bìrí olorì darapọ̀ mọ́ èrò ìnájà, Adégún ń d'Adéògún, Fáìlì di Fàlí,Adéẹgbẹ́ yípadà d'Adẹ̀gbẹ́, ọ̀rọ̀ àná di bámìín, Ayé yí bìrìpé, ajá padà sídìí èébì, gbogbo ẹ̀,gbògbò ẹ̀, nítorí àtijẹ.... Ẹni wagbádá sùn di dandan kó gbójú oorun wa kẹ̀kẹ́, Afàpótírọrí ò le è gbádùn oorun, ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí fún ẹni tó gbódó mì! Ibi a ti pé ó dàárọ̀, Yorùbá ní a kìí tún pé ẹ káalẹ́ mọ́, aláìnítìjú lè su sáàrin ọjà níta gbangba, ẹgbẹ́ tí aráabí ní ó ń ti àwọn lójú láti fọn rere rẹ̀ lọ́jọ́sí, òun ló kan asọ pọ̀ bí eégún lábala jó jàgínní yòdò wọ́nú ẹ̀ padà nítorí àti fi dandan láá wooko di Gómìnà. Ẹni tó lójú lojú tì, àti pé orúkọ èkuru yàtọ̀ sí t'Àkàrà gédéńgbé, kárìn kápọ̀ yíyẹ ní yẹni, bí i ti ọgbà ẹ̀wọ̀n kọ́, èyí ló mú onímọ̀ ẹ̀rọ Faozey Oládọ̀tun Nurudeen ní ààrin gbùngbùn Òyó àti Ayédẹ̀rọ̀ Ilẹ̀ Yorùbá, Shina Abíọ́lá Peller ní Àríwá Ọ̀yọ́ sọ pé ó tó gẹ́ ẹ́! Pé àwọn ò sìnà mọ́, ní wón bá tẹ̀lé ẹni tó mọ̀nà òtítọ́, Gómìnà Ṣèyí Mákindé wọnú ẹ