*Ọ̀PỌ̀LỌ́ Ò MỌ̀NÀ ODÒ MỌ́.. AJÁ TI PADÀ SÍDÌÍ ÈÉBÌ RẸ̀ℹ️ NI ṢÈYÍ MÁKINDÉ BÁ FI ÀBÁ ÈTÒ ÌSÚNÁ ỌDÚN TÓ Ń BỌ̀ SỌ WỌ́N DEGBÉRE....! Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Abbas, Ọ̀kan gbóògì nínú Ẹgbẹ́ GSM Advocates


 

 Èké dáyé, aásà dàpòmu, ìgbà yí bìrí olorì darapọ̀ mọ́ èrò ìnájà, Adégún ń d'Adéògún, Fáìlì di Fàlí,Adéẹgbẹ́ yípadà d'Adẹ̀gbẹ́, ọ̀rọ̀ àná di bámìín, Ayé yí bìrìpé, ajá padà sídìí èébì, gbogbo ẹ̀,gbògbò ẹ̀, nítorí àtijẹ....


  Ẹni wagbádá sùn di dandan kó gbójú oorun wa kẹ̀kẹ́, Afàpótírọrí ò le è gbádùn oorun, ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí fún ẹni tó gbódó mì!


Ibi a ti pé ó dàárọ̀, Yorùbá ní a kìí tún pé ẹ káalẹ́ mọ́, aláìnítìjú lè su sáàrin ọjà níta gbangba, ẹgbẹ́ tí aráabí ní ó ń ti àwọn lójú láti fọn rere rẹ̀ lọ́jọ́sí, òun ló kan asọ pọ̀ bí eégún lábala jó jàgínní yòdò wọ́nú ẹ̀ padà nítorí àti fi dandan láá wooko di Gómìnà. 

  

Ẹni tó lójú lojú tì, àti pé orúkọ èkuru yàtọ̀ sí t'Àkàrà gédéńgbé, kárìn kápọ̀ yíyẹ ní yẹni, bí i ti ọgbà ẹ̀wọ̀n kọ́, èyí ló mú onímọ̀ ẹ̀rọ Faozey Oládọ̀tun Nurudeen ní ààrin gbùngbùn Òyó àti  Ayédẹ̀rọ̀ Ilẹ̀ Yorùbá, Shina Abíọ́lá Peller ní Àríwá Ọ̀yọ́ sọ pé ó tó gẹ́ ẹ́! Pé àwọn ò sìnà mọ́, ní wón bá tẹ̀lé ẹni tó mọ̀nà òtítọ́, Gómìnà Ṣèyí Mákindé wọnú ẹgbẹ́ Alábùradà lọ, wọ́n ní kí aráabí ó máa lọ dá jó ijó ẹ̀sín jàgínní yòdò!


Onírìkíṣí ń múnú pète àbòsí, Oníjàm̀bá ń gbèrò ìkà, eré ayò ọdún mẹta ààbọ̀ sí àsìkò yìí ni aráabí àti ẹgbẹ́ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ète rẹ látìwòyí, wọ́n ń fi ẹnu sáátá àbá ètò ìsúná tó làmi laaka jùlọ tí yó mú ìràpadà bá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kúrò nínú ẹ̀bù ẹ̀yìn tí yíyọ owó ìrànwọ́ orí epo rọ̀bì mú bá ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yìí, ní wọ́n bá ń sunkún kiri bí egbére, wọ́n ń fẹkún sògbérè bí ìgbà tí àwọn ọdẹ ń sùnrèmọ̀jé níbi aré ìsípà, Ọkọ Olúfúnnkẹ́ bu ata sí wọn lójú ọgbẹ́, wọ́n ń ké rara, Ṣèyí Mákindé ti da gúgúrú wàhálà sí wọn lágbada ó ní kí wọn ó máa yan án nìsó, ẹ̀yin náà ẹ w'ẹnu ilẹ̀ kí ẹ w'ẹnu okọ́, ẹ wo gbogbo iṣẹ́ ribiribi tí ọmọ Mákindé ń gbé ṣe kárí ilé kárí oko, iṣẹ́ sáà Kejì yìí tún lé-kenkà ju ti àkọ́kọ́,Àṣeyọrí Ṣèyí ń fọ wọn lórí kìí ṣe Àwàdà!


 Irọ́ ni, Ṣèyí Mákindé ti di imú, ọwọ́ ahọ́n kò le è tó imú láéláé, lẹ́yìn lolobe so, ẹ̀yìn lọmọ adìẹ ń tọ 'yà ẹ̀...!


Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Abbas

Ọ̀kan gbóògì nínú Ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES

Ìjọba ìbílẹ̀ iwọ̀ òòrùn ọ̀yọ́


Comments

Popular posts from this blog

Just in : Olubadan of Ibadanland Oba Mohood Lekan Balogun Joins Ancestors

Profile of Owolabi Olakulehin the Next Olubadan Of Ibadan

Akeem Olatunji Lays Foundation For The Construction Of A New Police Station In Oluyole LG... ...Unites Fictionalized Islamic Body In Oluyole LG